YBH 385

GBO ase ti Jesu pa

1. GBO ase ti Jesu pa,
“Lo wasu ‘hinrere Mi,
Enikeni t’ o gbagbo,
T’ a si tebomi, yio la.”

2. Jesu, mo gbo oro Re,
Emi tumo re fun mi,
Ihinrere Re l’ adun,
O si kun fun itunu.

3. Mo sa di agbelebu,
Nitoriti mo gbogbo
Pe O ki yio ta mi nu,
B’ ese mi ti le po to.

4. Mo wa lati s’ ase Re,
Oluwa, ran mi lowo,
Atunbi ni mo toro,
Fifun mi b’ ileri Re.

5. Alaimo, mo wa mokun,
Ri mi sinu iku Re,
Lehin na ji mi dide,
Ninu ewa ‘sodomo.

(Visited 200 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you