1. GBO ohun t’ o dun lat’ oke
Si Jesu l’ odo Jordani,
Eri fun gbogbo araiye,
“Eyi l’ ayanfe Omo Mi.”
2. Alailese, Eni pipe,
Sugbon nitorit’ a pase
Iwenumo ninu odo,
O f’ ara Re se apere.
3. Omo okan aiya Baba,
Igbala fun gbogbo eda,
Orisun iye elese,
Jordani t’ oke Kalfari.
4. Wa, tele Olugbala re,
Ninu ase ilo s’ odo,
Apere iba Jesu ku,
Ati ajinde pelu Re.
5. Wa, ma tan idi asiri
T’ o wu Oluwa lati bo,
F’ igboran saju, nikehin
Ere re y’o fi ara han.
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.