1. ELESE, nipa ‘jewo re
Si itiju Jesu,
Si irora at’ iku Re
Lori agbelebu.
2. Si imo ‘ra re l’ elese,
Ati eni egbe,
Ti ko le duro niwaju
Ofin at’ idajo.
3. Ijewo re pe iku Re,
Bi ti Omo Baba,
L’ o le fun o n’ iwenumo
Ati idariji.
4. A mura bi egbe mimo
Ti a ti f’ eje ra,
Lati sin O de orisun,
Ibi iwosan re.
5. Fi igbagbo gba ase na,
Ti Jesu se l’ ogo,
Ani, ase itebomi,
Bi t’ odo Jordani.
6. Imisi Baba at’ Omo,
At’ Olorun Emi,
K’ o fun o ni isod’ omo,
At’ iye ailopin.
(Visited 196 times, 1 visits today)