1. WO, awon t’ o ‘so ala,
Nwon duro leti odo,
Nwon k’ ehin s’ aiye at’ esu,
Nwon ntele Atebomi;
Nwon si nreti,
Lati se ase Jesu.
2. Wo bi nwon ti duro l’ eru,
Sugbon pelu ireti,
Nwon mo pe Olugbala won
L’ O pase odo lilo,
Jordan’ tutu,
Sugbon igbagbo gbona.
3. Si wo awon arakunrin –
Egbon nwon ninu Jesu,
Wo bi awon tin a ‘wo ife
Nwon sa ti dabi nwon ri,
Nisisiyi,
Nwon ny’ ayo idariji.
4. Lo, tele Olugbala nyin;
E f’ oju igbagbo ri;
A! orun si, Emi Baba
Si nke lat’ oke wipe,
“Awon nwonyi
Ni ayanfe omo Mi.”
(Visited 194 times, 1 visits today)