1. GBATI mo ri agbelebu,
Ti a kan Oba-ogo mo,
Mo ka gbogbo oro s’ ofo,
Mo kegan gbogbo ogo mi.
2. K’ a ma se gbo pe mo nhale,
B’ o ye n’ iku Oluwa mi,
Gbogbo nkan asan ti mo fe,
Mo da sile fun eje Re.
3. Wo lat’ ori, owo, ese;
B’ ikanu at’ ife ti nsan;
‘Banuje at’ ife papo,
A f’ egun se ade ogo.
4. Gbogbo aiye ‘ba je t’ emi,
Ebun abere ni fun mi;
Ife nla ti nyanilenu,
Gba gbogbo okan, emi mi.
(Visited 1,087 times, 1 visits today)