1. GBOGBO eje eran,
Ti pepe awon ju,
Ko le f’ okan l’ Alafia,
Ko le we eri nu.
2. Kristi Od’-agutan,
M’ ese wa gbogbo lo;
Ebo t’ o ni oruko nla,
T’ o ju eje won lo.
3. Mo f’ igbagbo gb’ owo
Le ori Re owon,
B’ eniti o ronupiwada,
Mo jewo ese mi.
4. Okan mi pada wo
Eru ti O ti ru;
Nigbati a kan O mo ‘gi,
Ese re wa nibe.
(Visited 399 times, 1 visits today)