1. NIWAJU ite anu Re,
Jesu, a tun ko ‘ra wa de,
A wa toro idariji,
Fun majemu t’ a ti baje.
2. A wa se otun ileri,
Ipa Re l’ o o le di wa mu,
Lati ma to awon ‘mo wa
Si inu isin pipe Re.
3. Ran wa lowo lati ma wa
‘Gbala awon ojulumo;
K’ a le ma hu iwa eto,
K’ a rin dede l’ oju aiye.
4. Jek’ a le se b’ ileri wa,
Lati ma je olotito;
K’ a fi ara wa s’ apere
Ninu iwa at’ ise wa.
5. K’ a takete si aheso,
At’ isoro eni lehin;
K’ a mase binu rekoja,
K’ oya w a lati mu ‘ja tan.
6. K’ a si ma toju ara wa
Ninu ife arakunrin;
Ki a ma se iranlowo
Ninu aisan at’ iponju.
7. Ninu ise rere gbogbo,
Mu w ape, Olugbala wa;
Si jek’ a le se ife Re
B’ awon mimo tin se l’ orun.
(Visited 575 times, 1 visits today)