YBH 401

JESU a de l’ ojo oni

1. JESU a de l’ ojo oni
Lati se ase Re,
Jo masai wa si arin wa,
K’ O f’ ola Re ran wa.

2. Awa de pelu ese wa,
Nipa or’-ofe Re,
Lati je ninu ara Re.
Mu ninu eje Re.

3. Ese wa papoju, Jesu,
Ojojumo l’ a nda,
Sibe ma jek’ eru ba wa
Lati ba O jeun.

4. Jek’ a sunmo O bi omo,
K’ a toro ‘dariji,
K’ a mo pe Baba ki yio je
Ki omo Re segbe.

5. Bi ao ti je akara na,
Eun wa ni igbagbo;
Si jek’ a fi adura mu
N’nu ago eje Re.

6. K’ a to kuro niwaju Re,
Fun wa n’ inu didun,
K’ a mo p’ a ti ba O pade,
Pe a ti ba O je.

(Visited 616 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you