YBH 402

O FUN mi l’ edidi

1. O FUN mi l’ edidi,
‘Gbese nla ti mo je;
B’ O ti fun mi, O si rerin
Pe, “Mase gbegbe Mi!”

2. O fun mi l’ edidi,
O san igbese na,
B’ o ti fun mi, O si rerin
Wipe, “Ma ran ti Mi!”

3. Ngo p’ edidi na mo,
B’ igbese tile tan,
O nso ife Enit’ o san
Igbese na fun mi.

4. Mo wo, mo si rerin,
Mo tun wo, mo sokun;
Eri ife Re si mi ni,
Ngo toju re titi.

5. Ki tun s’ edidi mo,
Sugbon iranti ni!
Pe gbogbo igbese mi ni
Emmanueli san.

(Visited 10,939 times, 9 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you