YBH 404

PELU iwa mimo, b’ Oluwa s’ oro

1. PELU iwa mimo, b’ Oluwa s’ oro
Be ‘nu Re n’ gbagbogbo je onje iye,
B’ onigbagbo s’ ore, Ran ailera lowo;
Ma gbagbe nigbakan, wa ibukun Re.

2. Pelu iwa mimo, Aiye nkoja lo,
Gbadura ni koko, si Jesu nikan
B’ iwo ba now Jesu, wo yio dabi Re,
Awon ore yio ri Jesu n’nu ‘wa re.

3. Pelu iwa mimo, je k’ On ma to o;
Ohun t’ o wu ko de, ma foya rara;
Banuje tab’ ayo, tele Jesu re,
Ma wo Olugbala, gbeke l’ oro Re.

4. Pelu iwa mimo, f’ okan re bale,
F’ On s ‘alakoso iwa on ise re;
Emi Re yio to o, s’ orisun ife,
Yio si mu o ye, ibugbe orun.

(Visited 566 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you