YBH 405

ALABUKUN n’ isun eje

1. ALABUKUN n’ isun eje,
T’ a fi han elese aiye;
Olubukun n’ om Olorun,
Nipa ‘na Re la wow a san,
Bi mo ti nu lo l’ agbo Re
Ti mo m’ egbe ba okan mi
F’ eje Od’ Agutan we mi
Emi o si fun ju yinyin lo.

Refrain
Fun ju yinyin lo
Fun ju yinyin lo
We mi nin’ eje Odagutan
Em’ o si fun ju yinyin lo.

2. Egun ni ade ori Re,
Agbelebu si l’ eru Re,
Ibanuje Re po julo,
Sugbon ko jiya na lasan
Ki a mu mi lo s’ isun na,
Ti nsan lati foe se mi nu
F’ eje T’ O ta sile we mi
Em o si fun ju yinyin lo.

Refrain
Fun ju yinyin lo
Fun ju yinyin lo
We mi nin’ eje Odagutan
Em’ o si fun ju yinyin lo.

3. Baba mo sako lodo Re,
Nigba pupo l’ okan mi nse;
Ese mi po o pan yanyan,
Ko s’ omi t’ o le we won mo,
Jesu mo wa si odo Re,
Mo gbekele ileri Re;
Fi eje mimo Re we mi,
Emi o si fun ju yinyin lo.

Refrain
Fun ju yinyin lo
Fun ju yinyin lo
We mi nin’ eje Odagutan
Em’ o si fun ju yinyin lo.

(Visited 175 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you