1. “LO wasu Mi,” l’ Oluwa wi:
Wi f’ aiye k’ o gba ore Mi;
Enit’ o gb’ oro Mi y’o la,
En’ti ko gbagbo y’o segbe.
2. “Ngo jek’ a mo ase nyin nla,
Eo si ri p’ oto n’ ihin Mi,
Nipa ise ti mo ti se
At’ ise ‘yanu t’ e o se.”
3. “Ko gogb’ orile l’ ase Mi;
Mo wa l’ ehin nyin de opin;
Agbara gbogbo l’ a fun Mi;
Mo le parun, mo le gbala.”
4. O wi, ‘mole tan l’ oju Re;
O gun sanma lo si orun;
Nwon si tan ‘hin ore-ofe
Olorun won yika aiye.
(Visited 127 times, 1 visits today)