1. IJINLE l’ oro Re, Jesu,
Tani le tumo re?
Tani gbon to! tani mo to!
Tal’ oye re po to!
2. Tani le si Bibeli re,
K’ irewesi ma mu?
Enikeni t’ o wu k’ o je
T’ o ba rant’ ese re.
3. Se alufa Re ni pipe
T’ o wu O, t’ O si yan;
Pa mo larin iji aiye
Ati idanwo re.
4. K’ o le ma rin n’ iwa mimo
Niwaju enia Re;
K’ o le f’ ara re s’ apere
Imole ododo.
5. Nigbat’ o ba duro n’waju
Awon t’ O rapada,
B’ ibawi tabi iyin ni
K’ o je bi oro Re.
6. Tu ibukun Re s’ ori re,
K’ Emi Re ma bag be,
Bo o k’ o le waon Tire,
Pelu onje emi.
(Visited 260 times, 1 visits today)