1. OWO l’ eni ororo Re,
L’ ojise oro mimo Re
Ipo eni owo l’ o wa,
Jek a f’ iyin at’ ola fun.
2. Ipo elegbe n’ ipo re,
Aso ti ko fe abawon,
Jek’ a fi ife ran lowo,
K’ a fi irele gb’ oro re.
3. Niwon b’ o ti wu O lati
Fi se oluso emi wa,
Fun ni suru lati to wa,
Ati opo if’ ara da.
4. Ma jek’ ise wa mu binu,
Ki iwa wa tan si subu;
Fun l’ agbara bi ojo re,
B’ ipo re, fun l’ or’-ofe Re.
5. Jek’ a r’ ewa Re l’ ara re,
K’ o ma ran n’nu iwa pele,
K’ o mo ‘po re bi oluso,
K’ a mo ti wa b’ agutan re.
(Visited 688 times, 1 visits today)