YBH 412

KRIST’, nin’ ogba Eden

1. KRIST’, nin’ ogba Eden,
L’ a gbe ti ri r’ ase yi,
Ase Tire,
P’ o ye f’ eni meji
Ki nwon jo ma gbe po,
Ki nwon jo ma rin po
Ninu aiye.

2. Nje, a k’ ara wa jo,
Lati se ase yi;
T’ ojo kini;
Jo, masai sokale,
K’ O wa si arin wa,
Pelu ibukun Re;
Sokale wa.

3. K’ awon mejeji yi,
T’ a fe lati so po,
Le wa fun O,
N’ gbagbogbo ma ko won
N’ ise won s’ ara won,
Ki nwon si le repo
Tit’ aiye won.

(Visited 524 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you