1. NI Kanani ti Galili,
Nib’ ase ‘gbeyawo,
Jesu f’ ara Re han nibe,
Pel’ awon ‘mo-ehin.
2. Jesu masai f’ ara Re han
Nibi ‘gbeyawo yi,
K’ O si fi ibukun Re fun
Oko ati aya.
3. Jeki nwon le wa n’ irepo,
Ni ojo aiye won;
K’ ife at’ orun wa so won,
K’ aiye ma le ja won.
4. Ki nwon ma ran ‘ra won lowo
Nipa ajumose;
Fi alafia Re kun won,
Fun won n’ itelorun.
5. Gege b’ ire ojo kini,
Ni ogba Edeni,
Ki nwon ma bi, kin won ma re,
Tit’ opin emi won.
(Visited 662 times, 1 visits today)