1. IRE t’ a su ni Eden’,
N’ igbeyawo ‘kini,
Ibukun t’ a bukun won
O wa sibesibe.
2. Sibe titi di oni,
N’ igbeyawo Kristian;
Olorun wa larin wa,
Lati sure fun wa.
3. Ire, kin won le ma bi,
Ki nwon si le ma re;
Ki nwon n’ idapo mimo
T’ enikan k’yo le tu.
4. Ba nip e, Baba, si fa
Obirin yi f’ oko;
Bi o ti Efa fun
Adam l’ ojo kini.
5. Ba ni pe Olugbala,
Si so owo won po,
B’ O ti so ara Re po
Pelu enia Re.
6. Ba wa pe, Emi Mimo,
F’ ibukun Re fun won;
Si se won ni asepe,
Gege b’ o ti ma se.
7. Fi nwon s’ abe abo Re,
K’ ibi kan ma ba won;
‘Gba nwon npara ile Re,
Ma toju okan won.
8. Pelu won l’ oj’ aiye won,
At’ oko at’ aya;
Titi nwon o d’ odo Re
N’ ile ayo l’ orun.
(Visited 4,901 times, 2 visits today)