YBH 415

JESU f’ ara han nitoto

1. JESU f’ ara han nitoto,
Nibi ase ‘yawo;
Oluwa, awa be O, wa
F’ ara re han nihin.

2. Fi ibukun Re fun awon
Ti o da ‘wo po yi;
F’ ojurere wo ‘dapo won,
Si bukun egbe won.

3. F’ ebun ife kun aiya won,
Fun won n’ itelorun;
Fi alafia Re kun won,
Si busi ini won.

4. F’ ife mimo so won d’ okan,
Ki nwon f’ ife Kristi
Mu aniyan ile fere;
Nipa ajumo se.

5. Je ki nwon ran ‘ra won lowo,
Ninu igbagbo won;
Ki nwon si ni omo rere,
Ti y’o gbe ‘le won ro.

(Visited 744 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you