1. SIMI le Oluwa -e gbo
Orin duru orun –
Simi le ife ailopin,
Si duro je,
2. Simi, iwo oko t’ o gba
Iyawo re loni;
Ninu Jesu, ‘yawo re ni
Titi aiye.
3. Iwo ti a fa owo re
F’ oko, n’nu ile yi,
Simi: Baba f’ edidi Re,
S’ ileri nyin.
4. E simi, enyin ore won
T’ e wa ba won pejo;
Olorun won, ati tin yin
Gba ohun won.
5. Simi: Jesu Oko Ijo
Duro ti nyin nihin:
Ninu idapo nyin, o nfa
Ijo mo ‘ra.
6. E simi: – Adaba Mimo
Sise Re ninu wa –
Simi le ife ailopin,
Si duro je.
(Visited 1,864 times, 1 visits today)