1. GBO l’ or’ ite Re, Alade,
F’ oniruru ‘bukun ranse,
B’ awon omo Re ti nwa O,
Gb’ adura t’ oro Re ko ni.
2. Wa, Emi Mimo lat’ oke,
F’ ife kun okan t’ o tutu;
A! s’ okan okuta d’ eran,
K’ O jek’ ipa Re di mimo.
3. Soro, oju t’ o da yio sun
Ekun ‘robinuje jade;
Nwon yio si f’ igbona okan
Wa ore ti nwon ko nani.
4. A! jek’ opo awon mimo
Duro n’ ilekun ile Re;
K’ olukuluku se ‘tara
Lati f’ ara rubo fun O.
(Visited 471 times, 1 visits today)