1. OLUWA, mo gbo pe Iwo
Nro ojo ‘bukun kiri;
Itunu fun okan are,
Ro ojo re s’ ori mi.
An’ emi!
Ro ojo re s’ ori mi!
2. Ma koja Baba Olore,
Bi ese mi tile po;
‘Wo le fi mi sile, sugbon
Jek’ anu Re ba le mi.
An’ emi, etc.
3. Ma koja mi, Olugbala
Jek’ emi le ro mo O;
Emi nwa oju rere Re,
Pe mi mo awon t’ O npe.
An’ emi, etc.
4. Ma koja mi, Emi Mimo,
‘Wo le la ‘ju afoju;
Eleri itoye Jesu,
Soro ase na si mi.
An’ emi, etc.
5. Mo ti sun fonfon nin’ ese,
Mo bi O binu koja;
Aiye ti de okan mi, jo
Tu mi, k’ o dariji mi.
An’ emi, etc.
6. Ife Olorun ti ki ye;
Eje Krist’ iyebiye;
Ore-ofe alainiwon;
Gbe gbogbo re ga n’nu mi.
An’ emi, etc.
7. Ma koja mi, dariji mi,
Fa mi roar, Oluwa;
‘Gba O nf’ ibukun f’ elomi,
Ma sai f’ ibukun fun mi.
An’ emi, etc.
(Visited 6,483 times, 4 visits today)