YBH 421

MA koja mi, Olugbala

1. MA koja mi, Olugbala,
Gbo adura mi;
‘Gbat’ Iwo ba np’ elomiran,
Mase koja mi!
Jesu! Jesu! Gbo adura mi,
Gbat’ Iwo ba np’ elomiran,
Mase koja mi.

2. N’ ite-anu jek’ emi ri
Itura didun;
Teduntedun ni mo wole,
Jo ran mi lowo.

3. N’ igbekele itoye Re,
L’ em’ o w’ oju Re;
Wo ‘banuje okan mi san,
F’ ife Re gba mi.

4. ‘Wo orisun itunu mi!
Ju ‘ye fun mi lo;
Tani mo ni l’ aiye, l’ orun
Bikose Iwo!

(Visited 12,905 times, 21 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you