1. JI ‘se Re nde Jesu!
Fi agbara Re han!
Fo ‘hun t’ o le j’ oku dide
Je k’ enia Re gbo.
2. Ji ‘se Re nde Jesu!
To orun iku yi!
Fi Emi agbara nla Re
Ji okan ti ntogbe!
3. Ji ‘se Re nde Jesu!
Mu k’ ongbe Re gbe wa!
Si mu k’ ebi pa okan wa
Fun onje iye na.
4. Ji ‘se Re nde Jesu!
Gbe oruko Re ga;
Mu k’ ife Re kun okan wa
Nipa Emi Mimo.
5. Ji ‘se Re nde Jesu!
Ro ‘jo itura nikan,
Ogo y’o je Tire nikan,
K’ ibukun je tiwa.
(Visited 6,788 times, 1 visits today)