1. A, JESU Alabukun,
A m’ orin ayo wa,
Ohun at’ okan ‘pe wa
L’ ayo l’ a gbe si O;
O ga, O si mo julo
Larin Angel’ l’ oke,
Sibe ninu ‘rele wa
Ife wa le kan O.
2. ‘Tori ninu anu Re
L’ O fi orun sile,
L’ O di omo kekere
Ni ibuje eran;
L’ O fi wa n’nu ikanu,
L’ O ku ‘ku itiju,
K’ O le f’ igbala f’ awon
T’ o gba oruko Re.
3. A, Olugbala owon,
Gba orin ife wa,
Gege b’ a tip e l’ ayo
Lati f’ iyin fun O;
B’ a ti ntun itan Re ro,
A wole n’ iyanu,
A, k’ a le ko orin Re
Nisiyi ati lai.
(Visited 273 times, 1 visits today)