1. E DIDE ki a si lorin,
K’ a yin Oluwa wa,
K’ a si dupe li owo Re,
F’ anfani idasi.
2. E dide ki a si korin,
K’ a yin Oluwa wa,
K’ a si dupe li owo Re
Fun oro mimo Re.
3. E dide ki a si korin,
K’ a yin Oluwa wa,
K’ a be E fun ‘ranwo orun,
T’ aiye ko le fun ni.
4. E dide ki a si korin,
B’ a si ti fe tuka,
Ki ohun na ti a ti ko,
Le je fun rere wa.
5. Nje ‘gbati a ba korin tan,
T’ a ba si s’ or’ ofe
K’ ibukun Re le ba wa,
Bi a ti nlo ‘le wa.
(Visited 247 times, 1 visits today)