1. OSE, ose t’ a nreti
A ki o pe “Ma wole,”
Iwo ni idunnu wa,
A kio s’ ole ninu re.
2. A wa ‘le eko loni,
At’ agba at’ ewe wa,
K’ Emi Re j’ oluko wa,
K’ agbara Re mu war o.
3. K’ awon agba ti nk’ eko
Ma p’ adanu ere na;
Fun nwon l’ ayo ninu Re,
Ki nwon le ba O joba.
4. Pel’ awon ‘mo were wa,
Ti nk’ eko n’nu ile yi,
Jeki nwon n’ iberu Re,
K’ eko won ma je lasan.
(Visited 295 times, 1 visits today)