YBH 434

LEHIN ‘jo mefa t’ O sise

1. LEHIN ‘jo mefa t’ O sise,
O simi ni ijo keje,
O pase fun wa k’ a se be,
Ki a si pa ojo na mo.

2. A wa lati m’ ase na se,
Ninu ile Re yi loni,
Niwon ‘gbat’ a mbe nihinyi,
Jek’ a mo p’ O mbe lodo wa.

3. Bi ao ti s’ iwe mimo Re,
Jek’ a le ka pelu ‘rele,
K’ a le mo pe ‘Wo l’ o nsoro,
Ki a teti si eko Re.

4. Tumo re fun wa fun ‘ra Re,
Alailogbon sa li awa,
Oro Re sa jinle pupo,
Oye wa ko si to fun u.

5. Pelu awon oluko wa,
Fi Emi Mimo Re fun won,
Ki O ma ko won n’ itumo,
B’ o ti wu k’ ijinle na to.

6. Nigbat’ a ba kuro nihin,
Jo masai pelu ona wa,
K’ a le ma se iranti Re
Titi ojo ‘simi miran.

(Visited 263 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you