1. K AWA to pari eko wa,
Awa f’ iyin fun O;
‘Tori ojo Re mimo yi,
Jesu Ore ewe.
2. Gbin oro Re si okan wa,
Gba wa lowo ese;
Ma je k’ a pada lehin Re,
Jesu, ore ewe.
3. Jesu jo bukun ile wa;
K’ a lo ojo yi ‘re;
K’ a le ri aye l’ odo Re,
Jesu ore ewe.
(Visited 311 times, 1 visits today)