YBH 437

MO fe ki ndabi Jesu

1. MO fe ki ndabi Jesu,
Ninu iwa pele;
Ko s’ enit’ o gboro ‘binu
L’ enu Re lekan ri.

2. Mo fe ki ndabi Jesu,
L’ adura ‘gbagbogbo;
Lori oke ni On nikan
Lo pade Baba Re.

3. Mo fe ki ndabi Jesu,
Emi ko ri ka pe
Bi nwon ti korira Re to,
O s’ enikan n’ ibi.

4. Mo fe ki ndabi Jesu,
Ninu ise rere;
K’ a le wi nipa t’ emi pe,
“O se ‘won t’o le se.”

5. Mo fe ki ndabi Jesu,
T’o f’ iyonu wipe,
“Je k’ omode wa s’ odo mi”
Mo fe je ipe Re.

6. Sugbon nko dabi Jesu
O si han gbangba be;
Jesu fun mi l’ ore-ofe
Se mi ki ndabi Re.

(Visited 5,808 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you