YBH 438

BI osun gbege eti ‘do

1. BI osun gbege eti ‘do,
Tutu minimini;
B’ igbo dudu eti omi,
B’ itanna ipa ‘do.

2. Be l’ omo na yio dagba,
Ti nrin l’ ona rere
T’ okan re nfa si Olorun,
Lat’ igba ewe re.

3. Ewe tutu l’ eba odo,
B’o pe a re danu;
Be n’ itanna ipa omi
Si nre l’ akoko re.

4. Ibukun ni fun omo na,
Ti nrin l’ ona Baba;
Oba ti ki pa ipo da,
Eni mimo lailai.

5. Oluwa, ‘Wo l’a gbakele,
Fun wa l’ ore-ofe;
L’ ewe l’ agba, ati n’iku,
Pa wa mo b’ omo Re.

(Visited 573 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you