1. NI kutu, mo de Oluwa
Lati wa oju Re,
Okan ongbe mi da ‘ku lo,
Lais’ ayo ore Re.
2. B’ o ti wu ki ase dun to,
Ko le te mi l’ orun;
B’ igba mo nto ore wo,
Ti mo ngbe ‘waju Re.
3. Aiye pa, pelu ayo re
Ko to m’ ori mi ya,
Ko to mu ayo mi goke,
Bi idariji Re.
4. Be, titi emi o pin,
Ngo bukun Oba mi,
Ngo gbe owo ebe soke,
Ngo f’ ete mi korin.
(Visited 355 times, 1 visits today)