1. OLORUN Baba, Krist’ Omo,
Ati Emi, Metalokan,
Gba ore ti a mu wa yi,
T’ a f’ ife onigbagbo se.
2. K’ imole oro Re f’ oye
F’ agba ati ewe nihin,
Gbin ore ni s’ okan pupo,
Ti gba ni la lowo ese.
3. Nihin, ki Jesu f’ ipa han,
Ti so okun di imole,
K’ O si s’ ilekun ‘fe paiya,
T’ o yo si ibukun loke.
4. Jesu Oluwa, Alade,
‘Wo t’ awon mimo nwole fun,
Gba ore iyin t’ a fun O,
K’ O si f’ ogo Re kun ‘le yi.
(Visited 213 times, 1 visits today)