1. NIHIN, l’ oko Re Oluwa,
A ko ‘le ‘rupe yi fun O,
Yan fun ‘bugbe Re Pataki,
K’ O si so lowo asise.
2. Gb’ enia Re ba nwa O nihin,
T’ elese mbebe fun iye,
Gbo lat’ ibugbe Re orun,
Gbat’ O ba gbo, k’ O dariji.
3. Gbat’ ojise Re ba nwasu
Ihinrere Jesu nihin,
Nip’ agbara oko Re nla,
K’ a ri ami on ‘se ‘yanu.
4. Gbat’ ohun ewe ba nkorin,
Hosanna s’ Oba won l’ oke,
K’ aiye at’ orun gberin na,
Ki angeli ko Hosanna.
5. K’ ogo Re ma f’ ihin ‘le lai,
Sibe, ma yan ‘le yi nikan,
K’ ijoba Re d’ okan gbogbo,
T’ ite Re si gbogbo aiya.
(Visited 221 times, 1 visits today)