1. OLORUN Baba, Ologo,
T’ O joko lor’ ite lai,
Awa omo Re teriba,
A nw’ ojure Re nikan;
Oluwa wa,
Jek’ anu Re han si wa.
2. Olorun Omo, ‘Lugbala,
T’ O duro n’ ite anu,
O ti jeje ojure Re
Nibit’ enia Re ba pe;
Alabukun,
Bukun wa b’ a ti duro.
3. Olorun Emi, to nwe ni,
‘Mole, Iye, Agbara,
Owo ina mimo loke,
Mu k’ oju Re dan si wa
Emi Mimo,
Se ago yi ni Tire.
4. Baba, Omo, ati Emi,
Ife ‘sokan, sokale;
Ki ore-ofe Re si wa
So ile yi di Tire;
Jehofa nla,
Ran ogo ‘dahun si wa.
(Visited 231 times, 1 visits today)