YBH 443

KRISTI n’ ipile wa

1. KRISTI n’ ipile wa,
Lori Re lao kole;
Awon mimo nikan,
L’ o ngb’ agbala orun.
Ireti wa
T’ ore aiye
T’ ayo ti mbo,
Wa n’nu ‘fe Re

2. Agbala mimo yi,
Y’o kun f’ orun iyin,
Ao korin iyin si,
Metalokan mimo.
Be lao f’ orun
Ayo kede
Oruko Re
Titi aiye.

3. Olorun Olore,
Fiye sini nihin;
Lati gba eje wa,
At’ ebe wa gbogbo;
K’o si f’ opo
Bukun dahun
Adura wa
Nigbagbogbo.

4. Nihin, je k’ ore Re
Ta’ ntoro l’ at’ orun
Bo s’ ori wa lekan.
K’ o ma sit un lo mo,
Tit’ ojo na
T’ ao s’ akojo
Awon mimo
Sib’ isimi.

(Visited 1,153 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you