1. LAT’ oke tutu Grinland,
Lati okun india,
Nib’ odo orun Afrik’,
Nsan ‘yanrin wura won;
Lat’ opo odo ‘gbani,
Lati igbe ope,
A nlo ki a le gba won,
kuro n’nu sina won.
2. Afefe orun didun,
Nfe jeje ni seilon;
Bi ohun t’a nri dara,
Enia l’o buru;
Lasan lasan l’Olorun
Nt’ebun Re gbogbo ka,
Keferi, n’nu ‘foju won,
Nwole bo okuta.
3. Nje awa ti a moye
Nipa ogbon orun,
O to k’a f’imole du
Awon t’o wa l’okun?
Igbala, a, igbala!
Funrere ayo na
Titi gbogbo orile
Yio mo Messia.
4. Efufu, mu ‘hin re lo,
Ati enyin odo;
Titi, bi okun ogo
Yio tan yi aiye ka;
Tit’ Od’agutan t’a pa
Fun irapada wa
Yio pada wa joba
L’alafia lailai.
(Visited 171 times, 1 visits today)