YBH 445

GBO ohun Jesu ti nke pe

1. GBO ohun Jesu ti nke pe,
Tani yio sise loni?
Oko pon pupo sise loni?
Tani yio lo ka a?
Kikankikan l’ Oluwa npe,
Ebun nla l’ O fi fun o,
Tani yio f’ ayo dahun pe,
“Emi ni; ran mi, ran mi.

2. B’ iwo ko le la okun lo,
Lati wa ‘won keferi,
O le ri nwon nitosi re,
Nwon wa l’ enu-ona re;
B’ o ko le fi wura tore,
O le fi baba ore,
Die t’ o si se fun Jesu,
‘Yebiye ni l’ oju Re.

3. B’ o ko le s’ oro b’ angeli,
B’ o ko le wasu bi Paul’,
Iwo le so t’ife Jesu,
Iwo le so ti iku Re;
B’ iwo ko le ji elese
Ninu ewu idajo,
‘Wo le ko awon omode
Li ona t’ Olugbala.

4. B’ iwo ko le k’ agbalagba,
Krist’ Olusagutan ni,
“Bo awon od’-agutan Mi,
Gbe onje ti won lodo:”
O le je pea won ‘mode
T’ o ti fi owo re to,
Ni yio wa larin oso re
Gbat’o ba de ‘le rere.

5. Ma jek’ enia gbo wipe,
“Ko si nkan t’ emi le se,”
Nigbat’ awon keferi nku,
Ti Oluwa si npe o,
F’ ayo gba ise t’ O ran o,
K’ ise Re je ayo re;
F’ ayo dahun gbat’ O pe o
Pe, “Emi ni yi, ran mi.”

(Visited 2,441 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you