1. IWO ti okunkun
Gb’ oro agbara Re,
T’ o si fo lo;
Gbo ti wa, a mbe O,
Nibit’ ihinrere,
Ko ti tan ‘mole re,
K’ imole wa.
2. ‘Wo t’ iye apa Re
Mu iriran w’ aiye,
At’ ilera:
Ilera ti inu,
Iriran ti okan,
Fun gbogbo enia
K’ imole wa.
3. Iwo Emi oto,
Ti o nf’ iye fun wa,
Fo kakiri:
Gbe fitila anu,
Fo ka oju omi,
Nibi okunkun nla,
K’ imole wa.
4. Metalokan Mimo,
Ogbon, Ife, Ipa,
Alabukun!
B’ igbi omi okun
Ti nyi ni ipa Re,
Be ka gbogbo aiye
K’ imole wa.
(Visited 1,386 times, 1 visits today)