YBH 448

WA, ma sise

1. WA, ma sise,
Tani gbodo s’ole ninu oko,
Gbati gbogbo enia nkore jo?
Kaluku ni Baba pase fun pe, –
“Sise loni.”

2. Wa, ma sise,
Gba ‘pe giga ti angeli ko ni –
Mu ‘hinrere to t’agba t’ewe lo;
“Ra ‘gba pada;” wawa l’akoko nlo,
Ile su tan.

3. Wa, ma sise,
Oko po, alagbase ko si to,
A nibi titun gba, a n’ipo ro:
Ohun ona jijin at’itosi
Nkigbe pe, “Wa.”

4. Wa, ma sise,
Le ‘yemeji on aigbagbo jina,
Ko s’alailera ti ko le se nkan:
Ailera l’Olorun a ma lo ju
Fun ‘se nla Re.

5. Wa, ma sise,
‘Simi ko si nigbat’ ise osan,
Titi orun yio fi wo l’ale,
Ti awa o si gbo ohun ni pe,
” O seun, omo.”

6. Wa, ma sise,
Lala na dun, ere na si daju.
‘Bukun f’ awon t’ o f’ ori ti d’ opin;
Ayo won, ‘simi won yio tip o to
Lod’ Oluwa.

(Visited 1,710 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you