1. WO b’ ikore tip o
L’ otun l’ osi wa,
Alagbase kere
L’ ogba Oluwa,
Enyin omo ‘bile,
Dide s’ igbala
Awon omo ‘ya wa
T’ o wa l’ okunkun.
Wo b’ ikore ti po
L’ otun l’ osi wa,
Alagbase kere
L’ ogba Oluwa.
2. Ogunlogo l’ o wa
Ninu aimokan,
Nrapala nin’ ese,
Lai mo ‘na ‘gbala;
Gbe ihamora wo,
Bi omo ogun,
Kede iku Jesu
Fun gbogbo eda.
3. Ranti pe Jesu ku
Fun gbogbo aiye:
Ma jek’ are mu nyin
Ni ise sise,
‘Le awon obi wa
Kun fun ‘borisa,
Nibe Esu joba,
Ase re mule.
4. Gb’ ohun rere ekun
Ni Masidonia,
T’ ile Afika wa
Pe k’ awa gba won;
Eni ba t’ oyin wo
Ko f’ enikeji,
Oluwa korira
Anikanjopon.
5. Ohun aiye wa yi
Ko ni ayole,
F’ owo ba, fi sile
L’ oruko re nje;
Ki a ka gbogbo re
B’ ebun abere,
Ki a ba le sise
‘Gbala keferi.
6. Ise aiye l’ ere
Oro kikojo,
Igbehin re asan
At’ ibanuje;
E jek’ a fr’ ara wa,
Ati owo wa,
Se ise igbala
N’ igba osan wa.