1. EFUN ‘pe na kikan,
Ipe ihinrere,
K’ o dun ja ‘ke ja ‘do,
L’ eti gbogbo eda;
Refrain
Odun idasile ti de,
Pada, elese, e pada.
2. Fun ‘pe t’ Odagutan
T’ a ti pa s’ etutu;
Je ki agbaiye mo
Agbara eje Re,
Refrain
Odun idasile ti de,
Pada, elese, e pada.
3. Enyin eru ese,
E so ‘ra nyin d’ omo,
Lowo Kristi Jesu
E gba omnira nyin.
Refrain
Odun idasile ti de,
Pada, elese, e pada.
4. Olori Alufa
L’ Olugbala ise,
O fi ‘ra Re rubo
Arukun, aruda.
Refrain
Odun idasile ti de,
Pada, elese, e pada.
5. Okan alare, wa,
Simi l’ aiya Jesu;
Onirobinuje,
Tujuka si ma yo
Refrain
Odun idasile ti de,
Pada, elese, e pada.
(Visited 9,177 times, 4 visits today)