1. IRANSE Oluwa!
E duro nid’ ise;
E toju oro Re mimo,
E ma sona Re sa,
2. Je k’ imole nyin tan,
E tun fitila se;
E d’ amure girigiri,
Oruko Re l’ eru.
3. Sora! L’ ase Jesu,
B’ a tin so ko jina,
B’ o ba kuku ti kan ‘lekun
Ki e si fun logan.
4. Iranse ‘re l’ eni
Ti a ba n’ ipo yi;
Ayo l’ on o fi r’ Oluwa;
Y’o f’ ola de l’ ade.
5. Kristi tikalare
Y’o te tabili fun,
Y’o gb’ ori iranse nag a
Larin egbe Angel’.
(Visited 544 times, 1 visits today)