1. JESU y’o joba ni gbogbo
Ibit’ a ba le ri orun;
‘Joba Re y’o tan kakiri,
‘Joba Re ki o n’ ipekun.
2. On l’ ao ma gb’adura si,
Awon oba y’o pe l’ Oba;
Oruko Re b’orun didun,
Y’o ba ebo oro goke.
3. Gbogbo oniruru ede,
Y’o f’ ile Re ko ‘rin didun;
Awon omode y’o jewo
Pe, ‘bukun won t’ odo Re wa.
4. ‘Bukun po nibit’ On joba;
A tu awon onde sile;
Awon alare si simi;
Alaini si ri ‘bukun gba.
5. Ki gbogbo eda k’ o dide,
Ki nwon f’ ola fun Oba won;
K’ Angel’ tun wa t’ awon t’ orin
Ki gbogb’ aiye jumo gbe ‘rin.
(Visited 1,907 times, 2 visits today)