1. GBO! Orin ti Jubili,
O dabi sisan ara;
Tabi bi kikun okun,
Gbat’ igbi re ba nlu ‘le
Halleluya! Olorun
Olodumare joba;
Halleluya! K’ oro na
Dun yi gbogbo aiye ka.
2. Halleluya! Gbo iro,
Lati aiye de orun,
Nji orin gbogbo eda,
L’ oke, n’ isale, yika;
Wo, Jehofa to sete
Ida w’ ako;-O p’ ase,
Awon ijoba aiye
Di ijoba Omo Re.
3. Y’o joba yi aiye ka,
Pelu agbara nlanla,
Y’o joba ‘gbati orun,
At’ aiye ba koja lo;
Opin de; lab’ opa Re
L’ ota enia subu:
Halleluya! Olorun
Ni gbogbo l’ ohun gbogbo.
(Visited 260 times, 1 visits today)