1. FUNRUGBIN l’ owuro,
Ma simi tit’ ale;
F’ eru on ‘yemeji sile
Ma fon s’ ibi gbogbo.
2. ‘Wo ko mo ‘yi ti nhu,
T’ oro tabi t’ ale;
Ore ofe yio pa mo
‘Bit’ o wu k’o bo si.
3. Yio si hu jade
L’ ewa tutu yoyo,
Beni y’o si dagba s’oke,
Y’o s’ eso nikehin
4. ‘Wo k’y’o sise lasan!
Ojo, iri, orun
Y’o dapo mo irinle wa
Fun ikore orun.
5. Nje nikehin ojo,
Nigbat’ opin ba de,
Awon Angel’ y’o si wa ko
Ikore lo s’ ile.
(Visited 397 times, 1 visits today)