1. ORO die fun Jesu;
Ore otito ni;
Wa tu okan wa ninu
Ohun t’o se fun o.
Oro die fun Jesu,
Yio gba wa l’ ona wa,
Oro die fun Jesu
S’ oro, k’ orin, gb’ adua.
2. Oro die fun Jesu,
Iwo ri ‘dariji,
Nipa ore ofe Re;
Lao fi de ‘le orun.
3. Oro die fun Jesu,
Ko le n’ ibanuje;
Mo le Olugbala mi
T’o f’ Emi Re fun mi.
4. Oro die fun Jesu
Ma je k’ akoko lo
Okan t’o ko se sile
Yio mu ‘banuje ba.
5. Oro die fun Jesu
Bi ‘gbagbo re nku lo,
Dide ninu are re
Fi yoku le l’owo.
(Visited 339 times, 1 visits today)