1. AGOGO ihinrere
Nlu lat’ ilu de ‘lu
‘Bukun ati ‘gbala ofe,
Ni nwon fun o at’ emi,
Olorun f’ araiye
T’ O fi Omo Re fun wa;
P’ enikeni ti o gb’ A gbo
Yio n’ iye ainipekun.
Refrain
‘Hinrere b’o ti nlu,
Lati ilu de ilu,
‘Hinrere, l’ ofe ni,
‘Hinrere to n’ibukun.
2. Agogo ihinrere
Npe wa si ase na,
Jo, ma ko ipe Oluwa
Ma si ko ‘pe or’ofe.
Akara ‘ye l’ Emi,
Je n’nu re okan ebi,
B’ese re pon bi ododo
‘Won y’o funfun bi owu.
Refrain
‘Hinrere b’o ti nlu,
Lati ilu de ilu,
‘Hinrere, l’ ofe ni,
‘Hinrere to n’ibukun.
3. Agogo na nma nkilo;
B’o ti nlu lojojumo,
Fun awon ti o njafara
Nipa ohun t’o ba won,
S’ asala f’ emi re,
Ma duro ni petele,
Mase bi oju wo ehin re,
Ki egbe mase ba o.
Refrain
‘Hinrere b’o ti nlu,
Lati ilu de ilu,
‘Hinrere, l’ ofe ni,
‘Hinrere to n’ibukun.
4. Ayo ni agogo na,
Fi nlu kakiri aiye,
Nso nipa ti dariji
Ti Jesu yio fi fun wa,
‘Hinrere t’ ayo nla
L’ omu wa fun gbogb’ enia,
Fun o l’ a bi Olugbala
Krist Oluwa at’ Oba.
Refrain
‘Hinrere b’o ti nlu,
Lati ilu de ilu,
‘Hinrere, l’ ofe ni,
‘Hinrere to n’ibukun.