YBH 460

ATI gbo iro didun

1. ATI gbo iro didun,
Jesu le gba ni la,
Ji ‘se na yi aiye ka,
Jesu le gba ni la,
K’e so fun gbogbo aiye
Gun oke, koja okun,
Oluwa pase k’e lo
Jesu le gba ni la.

2. E soo l’ ori ‘ji okun
Jesu le gba ni la
Wi fun gbogbo elese,
Jesu le gba ni la,
E korin, erekusu,
Gberin na, eyin okun;
Ki gbogbo aiye maa yo,
Jesu le gba ni la!

3. Korin na s’oke kikan
Jesu le gba ni la;
Iku at’ ajinde Re
L’o ti fi gba ni la;
Korin ‘jee n’gba ‘banuje,
Gbat’ okan wa nfe anu
Korin ‘segun lor’ iku
Jesu le gba nila.

4. Afefe, gbohun soke
Jesu le gba ni la;
Gbogb’ oril’ ede, e yo,
Jesu le gba ni la,
Kede igbala ofe
Si gbogb’ orile aiye
Orin isegun wa ni –
Jesu le gba la.

(Visited 1,410 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you