1. KRISTI fun gbogb’ aiye
Ise nla naa bere
Egbegberun ni gbogb’ aiye,
Nfe gb’ oro ‘mo ‘Lorun
Nwon o ha ku si n’ ese
Lai gbo ‘ro Mimo Re
Lai ni Kristi Olugbala
‘Tori won ko gbo ri?
Ao dawo…. ao gbadura…..
Ao wasu Re lojojumo
K’ ogunlogo ni gbogbo aiye
Le mo ‘fe Oba wa.
2. Kristi fun gbogb’ aiye!
K’ a f’ oro Re ranse
S’ opo awon t’ o nku n’ese
Ki won le yi pada
Iku Krist’ ngba ni la,
Sugbon nwon ko le mo
Tit’ ao m’ebun ife wa wa
K’ awon ‘rans ele lo!
3. Kristi fun gbogb’ aiye!
‘Ranse Re yio kede
Igbala fun gbogbo eda
L’ oruko nla Jesu
Awa t’ a ko le lo
Wasu l’ ona to jin
Ao gbadura f’ awon to lo
Ao jeri n’bi t’ a wa.
(Visited 260 times, 1 visits today)