YBH 462

ILU mi, orin re

1. ILU mi, orin re,
Ilu mi omnira
Li emi nko;
Il’ awon baba mi,
Ile awon ero,
K’ orin omnira dun
L’ oke gbogbo.

2. Ilu t’ a gbe bi mi,
‘Le awon omnira,
Mo feran re;
Mo fe awon oke
At’ awon igbo re
Okan mi kun f’ ayo
Bi ti orun.

3. K’ afefe omnira,
Bi lu gbogbo igi,
Ki won ko ‘rin,
Ki gbogbo ahon ji,
Ki gbogb’ eda gberin,
K’ okuta ma dake
Lati ko ‘rin.

4. Olorun, Baba wa,
‘Wo t’ O da omnira,
L’a nko ‘rin si;
K’ ilu wa f’ imole
Ominira dan titi,
F’ ipa Re pa wa mo
Olorun wa.

(Visited 205 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you